Arakunrin kan ji ara-re gbe, osi fe gba owo to to ogota millionu (60million) lowo awon molebi re gege bi owo itanran.

2

Awon olopa ipinle Eko ti mu arakunrin kan eni to paro wipe awon ajinigbe ti ji oun gbe lati gba owo lowo awon molebi re.

Gege bi iroyin ti iwe iroyin Daily Post se, ogbeni Victor Udoh lo lo si ago olopa lati lo fi to won leti wipe awon ajinigbe ti ji aburo Ufom Edet Udoh gbe ni adugbo Liverpool ni Apapa ipinle Eko.

Agbenuso fun awon olopa, ASP Olarinde Famous-Cole so wipe lesekese ni awon olopa bere iwadi ati ise lori oro na eyi to si fa ti won fi ri odomodekunrin kan ti oruko re nje Paul Philips Okiemute. Leyin igba ti won fi oro wa Okemute lenu wo, lo jewo wipe Edet Udoh lo paro fun awon molebi re wipe won ji oun gbe lati le gba owo to to ogota millionu lowo awon molebi re.

lai pe ni owo awon olopa te arakunrin Ufom Edet Udoh na to si jewo wipe iro nioun pa, wipe oun nilo iranlowo lati fi bere ise ohun ni,ti oun si ro lokan lati paro wipe won ji oun gbe ki ohun ba le ri owo na gba.

O so wipe ile itura kan ni Iyana-ipaja lohun fi arapa mo si, ti oun o si jeun fun ojo meji gbako, ki o ba le da bi igba ti awon ajinigbe fi iya je ohun ni.

Oga agba awon olopa ni ipinle Eko, Fatai Owoseni ti pase wipe ki won tete gbe arakunrin na lo lati lo fi oju ba ile ejo.

Get more stuff like this
in your inbox

Subscribe to our mailing list and get interesting stuff and updates to your email inbox.

Thank you for subscribing.

Something went wrong.

2 COMMENTS

Leave a Reply Cancel reply