Awon agbofinro ipinle Eko ti mu baba-alawo ton soju egbe okunkun Badoo. +18

4

Awon omo ile ise olopa ati awon agbofinro ton soju ipinle Eko ti mu arakunrin kan ti oruko re nje Fatai Adebayo eni ti gbogbo eyan mo si Alese. Arakunrin na ni awon olopa gbo wipe ohun ni baba-alawo ton soju, to sin se ogun fun awon omo egbe okunkun badoo ton da alafia agbegbe ikorodu lamu ni ipinle Eko.

Arakunrin Adebayo na, omo odun merinlelogbon ton gbe ilu Imosan, ni opopona Ijebu-Ode, ni ipinle Ogun ni owo awon agbofinro ba leyin ti awon omo egbe badoo ti won mu ni nkan bi osu melo kan seyin ka. Orisirisi ogun ati awon ohun nkan abami ni won ba ninu ile arakunrin na.

Oga agba awon olopa ACP Tunji Disu nigba ton ba awon oniroyin soro so wipe, iwadi na sin te siwaju, o si so siwaju si wipe awon ti pinu lati tu isu de isale ikoko lori oro awon odaran ati omo egbe okunkun na.

Get more stuff like this
in your inbox

Subscribe to our mailing list and get interesting stuff and updates to your email inbox.

Thank you for subscribing.

Something went wrong.

4 COMMENTS

  • Leave a Reply Cancel reply