Kayefi nla leleyi. Omo ile iwe giga kan ge ori iya re ni ipinle Osun.

0

Awon agbofinro ti ipinle Osun ti mu odomode kunrin omo odun marunlelogun (25yrs) akeko ile iwe giga Adekunle Ajasin University ti ipinle Ondo, Ogbeni Joseph Mark eni to ge ori iya re Arabirin Christianah Mark ni inu ile won.

Alukoro ile ise olopa to wa ni ipinle Osun, arabirin Folashade Odoro nigba ton ba awon oniroyin soro so wipe isele Kayefi na sele ni No 25, Zone 5, Ajetomobi Street, Eko-Ende Road, Ikirun, ipinle Osun ni ojo aje ojo keta osu kejila. O so siwaju si wipe baba odaran na lo fi oro na to awon agbofinro leti nigba ti isele na sele tan. O so wipe baba odaran na, Ogbeni Adewale Mark, lo jade ni aro kutu-kutu ojo buruku na ni nkan bi ago marun abo idaji (5;30am) latilo ki ikan ninu awon ore re ni adugbo keji, nigba to pada de ile ni nkan bi ago mefa (6am) lo ti ba ori iyawo re lowo omo re Joseph.

 

Oga Olopa Odoro wa tan imole si oro na wipe oda wipe odaran na tin ya were ni, o so eleyi latari ayewo ti won se fun arakunrin na leyin igba ti won gbe lo si ago won. Iwadi to peye sin lo lori oro na, be ni won si ti sin oku ologbe Christianah.

 

Get more stuff like this
in your inbox

Subscribe to our mailing list and get interesting stuff and updates to your email inbox.

Thank you for subscribing.

Something went wrong.

Leave a Reply Cancel reply