O GA O!. Arabirin ojowu kan gba emi oko re nitori pe o fe iyawo keji ni ilu Osogbo.

2

Arabirin omo odunkandinlogoji (39yrs) kan ti oruko re n je Omotayo Salawudeen lo ti jewo fun awon agbofinro wipe ohun ni ohun gbe ise fun agbenipa lati gba emi oko re, ologbe Hakeem Salwudeen latari wipe o lo fe iyawo miran.

Arabirin ojowu na lo so wipe inu abiju lo bi ohun, ti esu si ya owo ohun lo. O so siwaju si wipe ohun ni ohun gbe ise fun odaran agbenipa ti won sese fi sile ni ogba ewon to wa ni ilu Ilesa, ogbeni Oladapo Dolapo omo odun merinlelogun (24yrs) lati ba ohun pa oko ohun.

Arabirin na jewo wipe eyan dada ni oko ohun, to si man toju awon omo meta ti Olorun fi jinki awon, sugbon ibinu wipe o lo fe obirin miran lo je ki ohun wu iru iwa ti ohun wu yi. O so wipe ohun fi timu-timu (Pillow) bo imu oko ohun leyin igba ti awon jo ni ajosepo tan ni inu ile won to wa ni agbegbe Hallelujah estate ni ilu Osogbo, ti Dolapo si fi obe gun arakunrin na pa.

O so wipe ohun kabamo wipe ohun wu iru iwa yi, ohun si toro aforiji lowo Olorun ati gbogbo awon molebi oko ohun.

Awon olopa ton soju ago olopa to wa ni agbegbe Dada estate ni ilu Osogbo, ipinle Osun, ti wa bere iwadi, ti won si ti setan lati gbe awon odaran mejeji na lo si ile ejo.

Get more stuff like this
in your inbox

Subscribe to our mailing list and get interesting stuff and updates to your email inbox.

Thank you for subscribing.

Something went wrong.

2 COMMENTS

Leave a Reply Cancel reply