OJO BURUKU ESU GBOMI MU; Awon agbebon (Gunmen) kan pa opolopo awon olujosin ni ile ijosin Katoliki Mimo (Catholic Church) kan ni Ozubulu, Ipinle Anambra

0
Ozubulu Church

Isele buruku kan to mu ibanuje wa si okan awon oludari ile ijosin Katoliki mimo ti St. Philip Catholic Church Amakwa Ozubulu ni ijoba ipinle Ekwusigo ni ipinle Anambra, waye ni nkan bi ago mefa aro, ni oni, nigba ti awon agbebon kan yalu ile ijosin na ti won si bere si yin ibon mo awon olujosin na.

Opolopo awon olujosin na lo so emi won nu, ti awon miran si farapa yana-yana. Awon agbofinro to soju ipinle na ti wa bere iwadi lati mo idi ti isele na fi waye ati wipe awon wo lo se okunfa isele na.

Awon to so emi won nu ninu ikolu na ati awon ti won farapa ni awon osise ati alomojuto ile ijosin na ti gbe lo si ile iwosan Nnamdi Azikiwe University Teaching Hospital ni ilu Nnewi.

Adura wa ni wipe ki Olorun te awon ologbe na si afefe ire ki o si fi oju awon amokunseka na han. Amin

 

Get more stuff like this
in your inbox

Subscribe to our mailing list and get interesting stuff and updates to your email inbox.

Thank you for subscribing.

Something went wrong.

Leave a Reply