Awon omo egbe agbaboolu Super Eagles na Indomitable Lions ti orilede Cameroon ni omi ayo merin si odo. (4-0).

Awon omo egbe agbaboolu Super Eagles loni, koju awon akegbe won lati orilede Cameroon ni papa idaraya Godswill Akpabio International Stadium, ni ilu Uyo, won si gbomi ewuro si won loju nigba ti won gba omi ayo merin sinu awon won, ti awon omo egbe agbaboolu Cameroon o ri ikankan da pada.

  Odion Ighalo, John Obi Mikel, Victor Moses ati Kelechi Iheanacho lo gba omi ayo na wole.