Igbakeji Aare Yemi Osinbajo ti da oga agba ajo DSS Ogbeni Lawal Daura duro lenu ise

0

Latari idena ti awon osise ajo DSS se loni ni ile igbimo asofin, ti won si ko lati fun awon Senito laye lati wo inu ibise won, Igbakeji Aare Yemi Osinbajo se atejade kan lati fi han wipe iwa ti ko boju mu rara ni isele na, to si lodi si eto ijoba orilede Nigeria gege bi ijoba alagbada.

Nitori na, Igbakeji Aare, eni ton soju Aare Buhari ti pase fun oga agba ajo DSS lati fi ise sile ni kai-kia, won si ti pinu lati bere iwadi, lati si fi mo okodoro oro na.

Ninu atejade ti o ti owo agbenuso fun igbakeji Aare ,ogbeni Laolu Akande jade, o je ko ye gbogbo eniyan wipe Aare o mo nipa isele na rara.

Get more stuff like this
in your inbox

Subscribe to our mailing list and get interesting stuff and updates to your email inbox.

Thank you for subscribing.

Something went wrong.

Leave a Reply