Oga olopa ni ipinle Ondo Aminu Mustapha ti ku ninu isele ijamba oko kan to sele ni opopona Ondo si Ore.

0

 

Ijoba ipinle Ondo ti fi idi ijamba oko to se iku pa oga olopa ni ipinle na ogbeni Aminu Mustapha mule. Isele na waye ni opopona Ondo si Ore ni agbegbe Omifon ni ijoba ipinle Odigbo ni ipinle Ondo ni irole ojo aiku nigba ti oga olopa na n’lo be awon molebi re. Iwadi fi ye wa wipe ikan ninu awon omo oga olopa na wa ninu oko ayokele ti won fin rin irinajo na sugbo ori ko omo na yo, o si wa ni ile iwosan nibi to tin gba itoju.

Agbenuso fun ile ise olopa ti ipinle Ondo ogbeni Femi Joseph, nigba ton ba awon akoroyin soro so wipe kayefi n’la ni iku Aminu Mustapha je fun awon, oso siwaju wipe awon o ni gbagbe gbogbo ise takun-takun ti oga olopa na ti gbe aye se. Adura wa ni wipe ki Olorun fi ori ji arakunrin na, ko si fun awon molebi re ni okan lile lati gba kadara. Amin.

Get more stuff like this
in your inbox

Subscribe to our mailing list and get interesting stuff and updates to your email inbox.

Thank you for subscribing.

Something went wrong.

Leave a Reply Cancel reply